Saamu 5
Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin fífọn. Saamu ti Dafidi. 
 1 Fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, Olúwa, 
kíyèsi àròyé mi. 
 2 Fi etí sílẹ̀ sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́, 
ọba mi àti Ọlọ́run mi, 
nítorí ìwọ ni mo gba àdúrà sí. 
 3 Ní òwúrọ̀, Olúwa, ìwọ yóò gbọ́ ohùn mi; 
ní òwúrọ̀, èmi yóò gbé ẹ̀bẹ̀ mi sí iwájú rẹ̀ 
èmi yóò sì dúró ní ìrètí. 
 4 Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tí ó ní inú dídùn sí búburú; 
bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi kò le è bá ọ gbé. 
 5 Àwọn agbéraga kò le è dúró 
níwájú rẹ̀. 
Ìwọ kórìíra gbogbo àwọn aṣebi; 
 6 ìwọ yóò pa àwọn tí ń ṣe èké run. 
Apani àti ẹni ẹ̀tàn ènìyàn 
ni Olúwa yóò kórìíra. 
 7 Ṣùgbọ́n èmi, nípa títóbi àánú rẹ̀, 
èmi yóò wá sínú ilé rẹ̀; 
ní tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni èmi yóò tẹríba 
sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀. 
 8 Tọ́ mi, Olúwa, nínú òdodo rẹ, 
nítorí àwọn ọ̀tá mi, 
mú ọ̀nà rẹ tọ́ níwájú mi. 
 9   Ro 3.13.Kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ẹnu wọn tí a lè gbàgbọ́; 
ọkàn wọn kún fún ìparun. 
Ọ̀nà ọ̀fun wọn ni isà òkú tí ó ṣí sílẹ̀; 
pẹ̀lú ahọ́n wọn ni wọ́n ń sọ ẹ̀tàn. 
 10 Dá wọn lẹ́bi Ọlọ́run! 
Jẹ́ kí rìkíṣí wọn jẹ́ ìṣubú wọn. 
Lé wọn jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, 
nítorí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ. 
 11 Ṣùgbọ́n, jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó sádi ọ́ kí ó yọ̀; 
jẹ kí wọn máa kọrin fún ayọ̀ títí. 
Tan ààbò rẹ sórí wọn, 
àti àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ yóò máa yọ̀ nínú rẹ. 
 12 Dájúdájú, Olúwa, ìwọ bùkún olódodo; 
ìwọ fi ojúrere rẹ yí wọn ká bí asà.