50
Ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli àti ìgbọ́ràn ìránṣẹ́ 
 1 Ohun tí Olúwa wí nìyìí: 
“Níbo ni ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ ìyá rẹ wà 
èyí tí mo fi lé e lọ? 
Tàbí èwo nínú àwọn olùyánilówó mi 
ni mo tà ọ́ fún? 
Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ni a fi tà ọ́; 
nítorí àìṣedéédéé rẹ ni a fi lé ìyá rẹ lọ. 
 2 Nígbà tí mo wá, èéṣe tí a kò fi rí ẹnìkan? 
Nígbà tí mo pè, èéṣe tí kò fi sí ẹnìkan láti dáhùn? 
Ọwọ́ mi a kúrú láti gbà ọ́? 
Èmi kò ha ní agbára láti gbà ọ́ bí? 
Nípa ìbáwí lásán, Èmi gbẹ omi òkun, 
Èmi yí àwọn odò sí aṣálẹ̀; 
àwọn ẹja wọn rà fún àìsí omi 
wọ́n sì kú fún òǹgbẹ. 
 3 Èmi fi òkùnkùn bo sánmọ̀ 
mo sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ ṣe ìbòrí rẹ̀.” 
 4  Olúwa Olódùmarè ti fún mi ni ahọ́n tí a fi iṣẹ́ rán, 
láti mọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè gbé àwọn aláàárẹ̀ ró. 
O jí mi láràárọ̀, 
o jí etí mi láti gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí à ń kọ́. 
 5  Olúwa Olódùmarè ti ṣí mi ní etí, 
bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ṣọ̀tẹ̀ rí; 
Èmi kò sì padà sẹ́yìn. 
 6 Mo ṣí ẹ̀yìn mi sílẹ̀ fún àwọn tí ó ń nà mí, 
àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi fún àwọn tí ń fa irùngbọ̀n mi; 
Èmi kò fi ojú mi pamọ́ 
kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́yà àti ìyọṣùtì sí. 
 7 Nítorí Olúwa Olódùmarè ràn mí lọ́wọ́, 
a kì yóò dójútì mí. 
Nítorí náà ni mo ṣe gbé ojú mi ró bí òkúta akọ 
èmi sì mọ pé, ojú kò ní tì mí. 
 8 Ẹni tí ó dá mi láre wà nítòsí. 
Ta ni ẹni náà tí yóò fẹ̀sùn kàn mí? 
Jẹ́ kí a kojú ara wa! 
Ta ni olùfisùn mi? 
Jẹ́ kí ó kò mí lójú! 
 9  Olúwa Olódùmarè ni ó ń ràn mí lọ́wọ́. 
Ta ni ẹni náà tí yóò dá mi lẹ́bi? 
Gbogbo wọn yóò gbó bí aṣọ; 
kòkòrò ni yóò sì jẹ wọn run. 
 10 Ta ni nínú yín tí ó bẹ̀rù Olúwa 
tí ó sì ń gbọ́rọ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nu? 
Jẹ́ kí ẹni tí ń rìn ní òkùnkùn 
tí kò ní ìmọ́lẹ̀, 
kí ó gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa 
kí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run rẹ̀. 
 11 Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gbogbo ẹ̀yin ti ń tanná 
tí ẹ sì ń fi pèsè iná ìléwọ́ fún ara yín, 
ẹ lọ, kí ẹ sì máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ iná yín, 
àti nínú ẹta iná tí ẹ ti dá. 
Èyí ni yóò jẹ́ tiyín láti ọwọ́ mi wá. 
Ẹ̀yin ó dùbúlẹ̀ nínú ìrora.