45
 1 “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún ẹni òróró rẹ̀, 
sí Kirusi, ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí mo dì mú 
láti dojú àwọn orílẹ̀-èdè bolẹ̀ níwájú rẹ̀ 
àti láti gba ohun ìjà àwọn ọba lọ́wọ́ wọn, 
láti ṣí àwọn ìlẹ̀kùn níwájú rẹ̀ 
tí ó fi jẹ́ pé a kì yóò ti àwọn ẹnu-ọ̀nà. 
 2 Èmi yóò lọ síwájú rẹ, 
Èmi ó sì tẹ́ àwọn òkè ńlá pẹrẹsẹ 
Èmi yóò fọ gbogbo ẹnu-ọ̀nà idẹ 
èmi ó sì gé ọ̀pá irin. 
 3 Èmi yóò sì fún ọ ní àwọn ọrọ̀ ibi òkùnkùn, 
ọrọ̀ tí a kó pamọ́ sí àwọn ibi tí ó fi ara sin, 
tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ yóò fi mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, 
Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ó pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ. 
 4 Nítorí Jakọbu ìránṣẹ́ mi 
àti Israẹli ẹni tí mo yàn, 
Mo pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ, 
mo sì gbé oyè kan kà ọ́ lórí 
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò gbà mí. 
 5 Èmi ni Olúwa, àti pé kò sí ẹlòmíràn; 
yàtọ̀ sí èmi kò sí ọlọ́run kan, 
Èmi yóò fún ọ ní okun, 
bí o kò tilẹ̀ tí ì gbà mí, 
 6 tí o fi jẹ́ pé láti ìlà-oòrùn 
títí dé ibi ìwọ̀ rẹ̀ 
kí ènìyàn le mọ̀, kò sí ẹnìkan lẹ́yìn mi. 
Èmi ni Olúwa, lẹ́yìn mi kò sí ẹlòmíràn mọ́. 
 7 Mo dá ìmọ́lẹ̀, mo sì dá òkùnkùn, 
Mo mú àlàáfíà wá, Mo sì dá àjálù; 
Èmi Olúwa ni ó ṣe nǹkan wọ̀nyí. 
 8 “Ìwọ ọ̀run lókè rọ òjò òdodo sílẹ̀; 
jẹ́ kí àwọsánmọ̀ kí ó rọ̀ ọ́ sílẹ̀. 
Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó yanu gbagada, 
jẹ́ kí ìgbàlà kí ó dìde sókè, 
jẹ́ kí òdodo kí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀; 
Èmi Olúwa ni ó ti dá a. 
 9   Isa 29.16; Ro 9.20.“Ègbé ni fún ènìyàn tí ó ń bá Ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà, 
ẹni tí òun jẹ́ àpáàdì kan láàrín àwọn àpáàdì tí ó wà lórí ilẹ̀. 
Ǹjẹ́ amọ̀ lè sọ fún amọ̀kòkò, pé: 
‘Kí ni ohun tí ò ń ṣe?’ 
Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ lè sọ pé, 
‘Òun kò ní ọwọ́?’ 
 10 Ègbé ni fún ẹni tí ó sọ fún baba rẹ̀ pé, 
‘Kí ni o bí?’ 
tàbí sí ìyá rẹ̀, 
‘Kí ni ìwọ ti bí?’ 
 11 “Ohun tí Olúwa wí nìyìí, 
Ẹni Mímọ́ Israẹli, àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀. 
Nípa ohun tí ó ń bọ̀, 
ǹjẹ́ o ń bi mí léèrè nípa àwọn ọmọ mi, 
tàbí kí o pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi bí? 
 12 Èmi ni ẹni tí ó dá ilẹ̀ ayé 
tí ó sì da ọmọ ènìyàn sórí i rẹ̀. 
Ọwọ́ mi ni ó ti ta àwọn ọ̀run; 
mo sì kó àwọn àgbájọ ìràwọ̀ rẹ̀ síta. 
 13 Èmi yóò gbé Kirusi sókè nínú òdodo mi. 
Èmi yóò mú kí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́. 
Òun yóò tún ìlú mi kọ́ 
yóò sì tú àwọn àtìpó mi sílẹ̀, 
ṣùgbọ́n kì í ṣe fún owó tàbí ẹ̀bùn kan, 
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.” 
“Àwọn èròjà ilẹ̀ Ejibiti àti àwọn ọjà ilẹ̀ Kuṣi, 
àti àwọn Sabeani— 
wọn yóò wá sọ́dọ̀ rẹ 
wọn yóò sì jẹ́ tìrẹ; 
wọn yóò máa wọ́ tẹ̀lé ọ lẹ́yìn, 
wọn yóò máa wá lọ́wọ̀ọ̀wọ́. 
Wọn yóò máa foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀, 
wọn yóò sì máa bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ pé, 
‘Nítòótọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ kò sì ṣí ẹlòmíràn; 
kò sí ọlọ́run mìíràn.’ ” 
 15 Nítòótọ́ ìwọ jẹ́ Ọlọ́run tí ó fi ara rẹ̀ pamọ́, 
Ìwọ Ọlọ́run àti Olùgbàlà Israẹli, 
 16 Gbogbo àwọn tí ó ń gbẹ́ ère ni ojú yóò tì 
wọn yóò sì kan àbùkù; 
gbogbo wọn ni yóò bọ́ sínú àbùkù papọ̀. 
pẹ̀lú ìgbàlà ayérayé; 
a kì yóò kàn yín lábùkù tàbí kí a dójútì yín, 
títí ayé àìnípẹ̀kun. 
 18 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí, 
ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run, 
Òun ni Ọlọ́run; 
ẹni tí ó mọ tí ó sì dá ayé, 
Òun ló ṣe é; 
Òun kò dá a láti wà lófo, 
ṣùgbọ́n ó ṣe é kí a lè máa gbé ibẹ̀, 
Òun wí pé: 
“Èmi ni Olúwa, 
kò sì ṣí ẹlòmíràn. 
 19 Èmi kò sọ̀rọ̀ níbi tí ó fi ara sin, 
láti ibìkan ní ilẹ̀ òkùnkùn, 
Èmi kò tí ì sọ fún àwọn ìran Jakọbu pé, 
‘Ẹ wá mi lórí asán.’ 
Èmi Olúwa sọ òtítọ́, 
Mo sì sọ èyí tí ó tọ̀nà. 
 20 “Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ sì wá; 
ẹ kórajọ, ẹ̀yin ìsáǹsá láti àwọn orílẹ̀-èdè wá. 
Aláìmọ̀kan ni àwọn tí ó ń ru ère igi káàkiri, 
tí wọ́n gbàdúrà sí àwọn òrìṣà tí kò le gba ni. 
 21   Ap 15.18.Jẹ́ kí a mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀, fihàn wá, 
jẹ́ kí wọn jọ dámọ̀ràn papọ̀. 
Ta ló ti sọ èyí lọ́jọ́ tí o ti pẹ́, 
ta ló ti wí èyí láti àtètèkọ́ṣe? 
Kì í ha á ṣe Èmi, Olúwa? 
Àti pé kò sí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi, 
Ọlọ́run olódodo àti olùgbàlà; 
kò sí ẹlòmíràn àfi èmi. 
 22 “Yípadà sí mi kí a sì gbà ọ́ là, 
ẹ̀yin ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé; 
nítorí Èmi ni Ọlọ́run kò sì ṣí ẹlòmíràn. 
 23   Ro 14.11; Fp 2.10-11.Nípa èmi tìkára mi ni mo ti búra, 
ẹnu mi ni ó ti sọ ọ́ pẹ̀lú gbogbo ipá mi, 
ọ̀rọ̀ náà tí a kì yóò lè parẹ́. 
Níwájú mi ni gbogbo orúnkún yóò wólẹ̀; 
nípa mi ni gbogbo ahọ́n yóò búra. 
 24 Wọn yóò sọ ní ti èmi, ‘Nínú Olúwa nìkan ni 
òdodo àti agbára wà.’ ” 
Gbogbo àwọn tí ó ti bínú sí; 
yóò wá sọ́dọ̀ rẹ̀ a ó sì dójútì wọn. 
 25 Ṣùgbọ́n nínú Olúwa gbogbo àwọn ìran Israẹli 
ni a ó rí ní òdodo, a o sì gbé wọn ga.